Mo ki yin l’okunrin l’obirin o. E ku ijo meta gbogbo yin. Se alaafia ni gbogbo yin wa? Emi naa dupe ibi ti olorun mu mi de o. Ona l’o po, mi o bati wa ko die ninu ero okan mi si ibi yi. Eyin ti e o gbo Yoruba e ma binu o. Bi o ti wun mi lati k’owe ni eni ni yi.
O ti to ojo meta nisiyin ti mo ti de abule blog yi, mo de dupe lowo gbogbo yin ti e ti wa ki mi ni ile mi. Emi naa a gbiyanju lati kan si yin. Mo so wipe mo ma maa k’owe ni ede ibile mi Yoruba ni ekan’kan. Mo ti n mu se o, mo si l’ero wipe eyin kan ni abule blog ma le ka ohun ti mo ko.
Ore mi Vera, ku ipalemo igeyawo e ni abule blog, mo gbe idi fun omidan Vera fun itan fabu “Gbogbo Obirin”, itan naa dun gidi gn ni, o si fi oju eeyan si ona fun apa kefa tio jade laipe.
Idije lati ri eni ti o fe omidan to dara ju ni abule blog yi ma dun gan o. Mo ti fi ara bale ka gbogbo e, mo si n reti esi idije naa. O seni laanu pee mi gan o tete gbo nipa idije naa, mba ti dije pelu won.
O wun ni ka jeran pe l’enu, onfa ona ofun ni o je. Nihin ni mo ma fi idi ti si ni eni. O tun di leyin igba die ki n to tun ko aroko ni ede mi ni abule blog.
Emi tiyin ni tooto, Emi, ara mi, ati emi gan gan!
6 comments:
Cheatin!!!
Alll I read is Vera!
Oya, start xplaining o
Ko ye mi (I think that's supposed to be "I don't understand")..lol
E jo explain :-)
E se
Babasola, e ma binu pe mi o wa ki yin lati'jo yii!
Gbogbo awon 'bulogi' to wa ni abule blog yii, wo n yi mi l'ori o!
Mo ti ko 'bulogi' yin sori t'emi. Mi o ni gbagbe mo!
A ma ma r'eti yin! Ki e ma pe ju o!
translation please!!! boy you tryna give people headaches... and LB you too are encouraging him....
inu mi dun lati kaa oro yi ni ede abinibi. nkan ti o lewa ni lati ri awon enia ti won ko fi ede won sile fun ti oyinbo, ti won si ngbe asa won laruge. igba akoko ti ngo ka bulogi yi ni eyi, o si je ohun ti owu mi lori pupo. ko da mo ni lati pe awon gbenagbena ki won laa igi mo mi lori ni.
ogbo ori o ni ntan ni be o, a o ma rire bara wa so ni o.
odi gba kan na
Inu mi dun lati ri pe awon omo iya mi ngbe ede wa laru ge.I have a blog in yoruba but somehow i couldnt get audience and gave up but seeing this,i think iam encourage to revive it
alajike.blogspot.com
Post a Comment